Hymn 560
Bi awa ba se Omo, nje awa li ajogun
Meter: 8.7.8.7.
Scripture: Rom. 8:17
1
Balogun! Olugbala wa,
Gb’ omo wonyi t’a bun O;
Se won ye fun ise Tiree,
Arole iye wonyi.
2
Arewa Baba wa orun,
Mu k’awon wonyi jo O
N’nu aworan Tire papa,
Lo won s’agbala oke.
3
Se won l’ agannigan mimo,
Omo-ogun t’o lera;
Ki won fo itegun esu.
Ki won si segun aye.
4
K’ oro Re dabi oguna,
L’enu awon omo Re;
Ti y’o jo ese l’ ajorun,
K’ ara ba le da sasa.
5
Pa won mo fun ’se ogo Re,
Ki won wa lailabawon;
KO won lati r’agbelebu,
Lojojumo aye won.
6
Bukun ’lana igbala yi,
Fun ire omo wonyi;
Gba won, to won, si ma SO won,
Nikeyin gb’ okan won la.