Hymn 561
IWO ki ise eru mo bikose omo.
Meter: 7.7.7.7.
Scripture: Gal. 4:7
1
fEwe ti Oba orun
Korin didun b’e ti nlo;
Korin ’yin Olugbala,
Ologo n’nu ise Re.
2
A nlo sodo Olorun
L’ona t’awon Baba rin;
Won si nyo nisisiyi,
Ayo won l’awa o ri.
3
crKorin agbo kekere,
E o simi n’ite Re;
Ib’apese ’joko yin,
Ibe si n’Ijoba yin.
4
Woke, Omo imole
Ilu Sion wa lokan;
Ibe n’ile wa titi,
Ibe l'a o r’Oluwa.
5
Ma sa, e duro l’ayo,
Ni eti ile ti yin;
Kristi Omo Baba nwi
Pe, Laifoya k’a ma lo.
6
mfJesu, a nlo l’ase Re,
A ko ’hun gbogbo sile
IWO ma j’ Amona wa
A o si ma ba O lo.