Hymn 562
Oluwa, emi nfe ibujoko Re, ibi ago Ola Re
Meter: 6.6.6.6.
Scripture: OD. 26:8
1
fOlorun awa fe
Ile t’ola Re wa;
Ayo ibugbe Re,
Ju gbogbo ayo lo.
2
mfIle adura ni,
Fun awon omo Re;
Jesu o wa nibe,
Lati gbo ebe wa.
3
Awa fe isun Re
Nibe l’Emi mimo
’Tu or’-ofe jade
Gegebi t’igba ni.
4
Awa fe ase Re
Kil'o dun to laye?
Nib’ awon oloto
Nri O ni ’tosi won.
5
A fe Oro iye,
Ti nso t’ alafia,
T’itunu n’nu ija
Atayo ti ki tan.
6
A fe korin anu,
T’a nri gba l’aye yi:
Sugbon awa fe mo
Orin ayo t’Orun.
7
Jesu Oluwa wa,
Bu si ’fe wa n’ihin;
K’a r’ oju Re l’orun
K’a ba ’won mimo sin.