Hymnize

CAC Hymn Collection

Hymn 563

Nibiti eni meji, tabi meta ba ko ara won JO li oruko Mi, nibe li Emi o wa li arin won.

Meter: L.M.

Scripture: Mat. 18:20

1

mfJesu, ni b’eni Re pade,

Nibe, won r’ite anu Re,

Nibe, won wa O, won ri O

Ibikibi ni ’le owo.

2

mfKo s’ogiri t’o se O mo,

O ngbe inu onirele;

Won mu O wa! bi won ba wa,

’Gba won nlo ‘le, won mu O lo.

3

mfOlus’agutan eni Re,

SO anu Re ’gbani d’otun

crSO adun oruko nla Re,

Fun okan ti nwa oju Re.

4

mfJe k’a ripa adua nihin,

Lati so ’gbagbo di lile

Lati gbe ife wa soke,

Lati gb’orun ka ’waju wa.

5

crOluwa’WO wa nitosi,

N’apa Re, de ’ti Re sile;

Si orun, sokale kankan;

Se gbogbo okan ni Tire.