Hymn 568
Oro mi li enyin ise.
Meter: H.7.8.7.D.
Scripture: Jn. 15:14
1
mpOre wo l'a ni bi Jesu
Ti o ru ’banuje wa;
Anfani wo l’o po bayi
Lati ma gbadura si?
Alafia pupo l’a nsonu
A si ti je’rora po,
mfN’tori a ko nfi gbogbo kan
S’adura niwaju Re.
2
mpIdanwo ha wa fun wa bi?
A ha ni wahala bi?
A ko gbodo so reti nu,
Sa gbadura s’Oluwa,
Ko s’oloto ore bi Re;
Ti o le ba wa daro
mfJesu ti mo ailera wa,
Sa gbadura s’Oluwa.
3
crEru ha nwo wa l’orun bi?
Aniyan ha po fun wa?
Olugbala je abo wa,
Sa gbadura s’Oluwa;
Awon ore ha sa O ti,
Sa gbadura s’Oluwa,
fY’o gbe o s’oke l’apa Re,
IWO y’o si ni ’tunu.