Hymn 57
Inu mi dun nigbati won wi fun mi pe, E je ka lo sile Oluwa.
Meter: C.M
Scripture: OD 122:1
1
fBi mo ti yo lati gb’oro
L’enu awon ore;
Pe, “Ni Sion’ni k’a pe si
K’a p’ojo mimo mo”
2
fMo f’onata at’ekun re;
Ile t’a se loso,
Ile t’a ko fun Olorun;
Lati fi anu han
3
S’agbala ile ayo na,
L’eya mimo si lo,
Omo Dafid’wa lor’ite,
O nda ejo nibe.
4
O gbo iyin at’igbe wa;
Bi ohun eru re
MpTi nya elese sib’egbe,
A nyo ni wariri
5
K’ibukun pelu ibe na
Ayo nigbakugba;
K’a fi ore ati ore,
F’awon ti nsin nibe
6
Okan mi bebe fun Sion’
Nigbati emi wa;
FNibe ni ‘batan at’ore
At’Olugbala wa.