Hymn 570
Emi ki yio jeki O lo, biko sepe O ba sure fun mi.
Meter: C.M.
Scripture: Gen. 32:26
1
mpOlus’agutan, toju wa
Li ojo ibi yi,
Fun gbogbo omo-eyin Re
N’ipa lati sona.
2
mpB’igba idanwo wa ba pe
T’iponju po fun wa,
Jek’ emi wa simi le O
L’adura aisimi.
3
mpF’ore-ofe emi ebe
Fun wa nipa gbagbo
K’a du titi a o r’oju Re,
T’ao si mo oko Re.
4
mpTiti O fun wa l’ara Re
Ati ife pipe,
K’eyi je igbe gbogbo wa
Nki o jeki O lo.
5
mfO ki O lo biko sepe
O s’oko re fun mi;
K’o f’igbala Re bukun mi,
Si je ndabi Re.
6
mfJe ki nroju Re kedere
’Gba m’ba d’ori-oke;
crNibi t’ar’ohun t’a gbagbo,
fT’adura di iyin.