Hymnize

CAC Hymn Collection

Hymn 572

Nibe lemi O pade re, emi o si ba O SORO lati oke ite anu wa.

Meter: L.M.

Scripture: Eks. 25:22

1

mfNinu gbogbo iji ti nja,

Ninu gbogbo igbi ponju,

Abo kan mbe, ti o daju

pO wa l’abe ite anu.

2

mfIbi kan wa ti Jesu nda

Ororo ayo s’ori wa;

O dun ju ibi gbogbo lo,

pIte-anu t’a f’eje won.

3

fIbi kan wa fun idapo;

Nibi ore npade ore;

L’airi ’ra nipa igbagbo,

pNwon y’ ite-anu kanna ka.

4

fA! nibo ni a ba sa si

Nigba ’danwo at’ iponju?

A ba se le bori esu

pBo sepe ko si ’te anu.

5

fA! bi idi l’a fo sibe

B’enipe aye ko si mo,

Orun wa pade okan wa,

pOgo si bo ite-anu.