Hymnize

CAC Hymn Collection

Hymn 573

E ma gbadura laisimi.

Meter: 7.6.7.6.D.

Scripture: 1 Tes. 5:17

1

mfLo, l’oro kutukutu,

Lo, ni osan gangan

Lo, ni igba asale,

Lo, ’loganjo oru;

Lo t’iwo t’inu rere

Gbagbe ohun aye

pSi kunle n’iyewu re,

Gbadura ni ’koko.

2

mfRanti awon t’o fe o

At’ awon t’iwo fe

Awon t’o korira re,

Si gbadura fun won;

Lehinna, toro ’bukun,

Fun ’wo tikalare,

Ninu adura re, ma

Pe oruko Jesu.

3

B’ aye lati gbadura

Ni ’koko ko ba si;

T’okan re fe gbadura

’Gbat’ ore yi o ka,

’Gbana, adura jeje,

Lati okan re wa

Y’o de odo Olorun

Alanu, Olufe.

4

fKo si ayo kan l’aye

T’o si ju eyi lo

Nit’ agbara t’a fun wa

Lati ma gbadura;

p’Gbat’inu re k’o ba dun

Wole, k’o gbadura,

crNinu ayo re gbogbo

Ranti or’ofe Re.