Hymn 574
Oju Oluwa mbe lara awon olododo, Eti Re si si igbe won.
Meter: C.M.
Scripture: OD. 34:15
1
mfOju kan mbe ti ki togbe
Nigbat’ ile ba su,
Eti kan si mbe ti k’ise
'Gbati orun ba wo.
2
Apa kan mbe ti ko le re
’Gba ’pa eniyan pin;
Ife kan mbe ti ko le ku
’Gba’fe aye ba ku.
3
Oju na nwo awon Seraf!
Apa na d’orun mu;
Eti na kun f’orin angel’,
Ife na ga l’oke.
4
mfIpa kan l’eniyan le lo,
’Gbat’ ipa gbogbo pin,
Lati ri oju at’apa
Ati ife nla na.
5
crIpa na ni adura wa
Ti nlo ’waju ite;
T’o nmi owo t’o s’aye ro
Lati mu ’gbala wa.