Hymnize

CAC Hymn Collection

Hymn 578

Igboiya lati wo inu ibi mimo nipase Eje Jesu.

Meter: S.M.

Scripture: Heb. 10:19

1

mfSa wo ite-anu,

Oro Re pe mi wa;

Nibe Jesu foju ’re han

Lati gbo adura.

2

pEje etutu ni

Ti a ti ta sile

Pese ebe t’o le bori

F’awon t’o nt’Olorun.

3

Bere ohun t’o fe,

’Wo ko le bere ju;

Eni t’O t’eje Re sile

Kini y’o fi du o?

4

Ife Re le fun mi,

Ju bi mo ti fe lo;

A ma fun eni t’o bere

Ju bi won ti n felo.

5

Fun wa l’aworan Re

At’ oju-rere Re;

Je ki nle sin O nihinyi,

Ki mba le ba O gbe.