Hymn 585
Nigbana ni O sore-ofe fun un, O si wipe, Gbaa kuro ninu lilo sinu iho, emi ti ri irapada!
Meter: L.M.
Scripture: Jobu 33:24
1
pBi mo ti kunle, Oluwa,
Ti mo nbe f’anu l’odo Re,
crWo t’Ore ’lese ti nku lo
Si tori Re gb’adura mi.
2
pMa ro ’tiju at’ebi mi,
At’ aimoye abawon mi,
crRot’ejeti Jesu ta’le
Fun ’dariji on iye mi.
3
mfRanti bi mo ti je Tire,
pTi mo je eda owo Re;
Ro b’okan mi ti fa s’ese
Bi ’danwo si ti yi mi ka.
4
mfA! ronu Oro mimo Re,
Ati gbogbo ileri Re,
Pe, WO O gbo adua titi
Ogo Re ni lati dasi.
5
pA! ma ro ti ’yemeji mi,
Ati ailo or’-ofe Re;
Ro ti omije Jesu mi,
Si fi ’toye Re di t’emi.
6
mfOju on eti Re ko se,
Agbara Re ko le ye lae
JO wo mi, okan mi wuwo,
pDa mi si, k’O ran mi lowo.