Hymnize

CAC Hymn Collection

Hymn 588

O ti ku fun gbogbo won, pe ki awon ti o wa laye ki o ma si pe wa laye fun ara won mo.

Meter: L.M.

Scripture: IIKor. 5:15

1

mfEmi ko le saini ife

Si Eleda mi t’O fe mi

Ni fifi emi Re lele

Ki emi elese le ye.

2

mpBi nko ba fe Oluwa mi

Emi y’o je alaimore;

pIku Re y’O ha jasan bi

Lori gbogbo ailera mi?

3

crOluwa jo fun mi n’ife

Ki nle ma feran Re titi

Ojo aye mi y’o d’ opin,

Ti uno fi wo ’nu ogo Re.

4

mfJesu, Ore loto l’O je,

Anu Re si duro laelae

Fun awon t’on se ife Re

Ni pipe n’nu iwa mimo.

5

fJesu t’O pa oro iku,

T’O si pa ise esu run;

T’ ese ko nipa l’ ori mi

Je ki nle ma se ’fe Re!