Hymn 589
Teti sile si ebe awon enia Re: ti nwon ba gbadura ki O si gbo li orun; gbo, ki O si dariji.
Meter: 7.7.7.7.D.
Scripture: I.A. Oba 8:30
1
mpJesu, ’Wo Od’agutan,
Ti O fara da ’rora,
’Wo t’ O se ’fe Baba Re
Ni fifi ese wa ji;
Awa ntoro anu Re
Ninu ebi ese wa;
Mu wa de ile ayo,
Ni ’kehin, k’a ba O gbe.
2
crNi ’gba idamu aye,
Ma j’Oluran lowo wa,
YO wa ninu idanwo
Ati l’owo ota wa;
Je k’a mo riri ’ku Re
Lori ’gi agbelebu,
’Gbagbogbo, je k’ okan wa
Ma ranti iya t’O je.
3
mfMu ki ife Re wa n’nu
Gbogbo okan ti nsako
Mu Won mo adun ati
Iye ati ajinde
T’iku Re mu wa fun won,
Tobe, nikehin ki Won
Ba le je alajopin
Ijoba ayeraye.