Hymnize

CAC Hymn Collection

Hymn 59

Ojo keje li ijo isimi Oluwa Olorun Re.

Meter: 6.6.7.6.7.6.7.6

Scripture: Eks. 20:10

1

mfOse, oso rere,

Iwo ojo simi;

O ye k’a fi ojo kan

Fun Olorun rere;

B’ojo mi ba m’ekun wa,

Iwo n’oju wa nu;

Iwo ti s’ojo ayo,

Emi fe dide re

2

fOse Ose rere,

A ki yo sise loni;

A o fi’se wa gbogbo

Fun aisimi ola,

Didan l’oju re ma dan,

‘Wo arewa ojo;

Ojo mi nso ti lala,

Iwo nso ti simi.

3

fOse, Ose rere

Ago tile nwipe,

F’eleda re l’ojo kan,

T’O fun o n’ijo mefa;

A o fi ‘se wa sile,

Lati lo sun nibe

Awa ati ore wa;

A o lo sile adua

4

mfOse, Ose rere,

Wakati re wu mi;

Ojo orun ni ‘wo se;

‘Wo apere orun;

MpOluwa, je ki njogun

‘Simi leyin iku;

Ki nle ma sin O titi,

Pelu eniyan Re.