Hymn 590
Bi O se ti emi, emi o kepe Olorun, yio si gba mi.
Meter: 10.10.10.10.
Scripture: OD. 55:16
1
mpBaba Orun mo na ’wo mi si O;
Iranlowo miran emi ko mo;
IWO t’O fewa bole bi aso
Fi ibukun Tire WO mi l’ewu.
2
Olori Ijo orun on aye,
Fi Emi Mimo Tire tun mi da;
Lo ero, okan ati emi mi,
K’emi le sise iwa saye mi.
3
crOlorun Eleda gbogbo aye,
Jeki nwa O, ki nri O, ki nfe O,
Ki nfe, ki n huwa ’fe si gbogb’ eniyan
Ki nsi fiwa jo O n’ise anu.
4
mfIsun ibukun, ife at’ayo,
Bi orun n’ijoba Re mu mi ran;
Ati lati aye yi lo k’emi
L’ayo at’ ibukun orun rere.