Hymnize

CAC Hymn Collection

Hymn 594

E ji iji ododo, ki e ma si dese.

Meter: 8.8.6.D.

Scripture: IKor. 15:34

1

crOlorun awamaridi

Ti ’fe Re nsi mi bo pele

Lat’ igba ewe mi,

JO, jeki nri ’nu okan mi

Ki nmo bi m’ba ni ’dalare

Nipa or’-ofe Re.

2

diB’oba se pe mo m’eru Re

Ti mo si f’okan oto je

Ipe atoke wa,

Busi or’-ofe t’O fun mi,

Si jek’ okan mi mo adun

Ifiji ife Re.

3

Nki o wa laini ife Re

Laini ’reti n’nu Oro Re,

Laini imo ’fiji;

Baba, nki o tan ’ra mi je,

Ki ns’ alaini Eleri na

Ti s’apere Orun.

4

crB’Eleri na ba ngbe n’nu mi

Ki o ha SO t’ilaja Re

T’ase nipa Jesu?

Un o fi igbagbo sunmo O,

Un o f’igboya ke pe, Baba!

Un o mo 'rami n’Tire.

5

mpOhunkohun t’o le dena,

Idariji ’fe Re si mi,

Ki ogo Re letan;

Jeki okan mi gba O gbo,

Fi gbogbo ese mi ji mi,

Si ko gbogbo won lo.

6

mfBaba, f’Omo Re han n’nu mi

Si jeki okan mi le mo

B’anu Re ti PO to;

F’asiri ife Re han mi,

Ma gbe ’nu okan mi titi

Nipa Emi Mimo.