Hymnize

CAC Hymn Collection

Hymn 599

Ki Olorun ki o sanu fun wa ki O si busi fun wa.

Meter: 8.7.8.7.D.

Scripture: OD. 67:1

1

fBaba wa, Eleda orun

Gbo ti wa l’akoko yi;

Fi ore ofe Re kun wa

K’a le j’omo eyin Re.

CHORUS

mfBukun wa, Baba, a mbe O

Dahun ebe wa loni,

Mase je k’awa lo lofo,

F’ ire kari wa, Baba.

2

crAwon t’o wa O n’gb’aye Re

Enikan, ko lo lofo;

B’aini gbogbo won ti po to,

L’O si bukun fun won to.

3

crIkunle wa j’okan soso

Sugbon ebe wa yato;

Alailera nfe iwosan,

Alaini ntoro ’bukun.

4

Fi ’dahun ’bere wa fun wa

B’ a ti nw’oju Re loni;

Ki gbogbo wa f’ayo wipe,

“ A ti ri idahun gba. ”