Hymnize

CAC Hymn Collection

Hymn 600

Emi kigbepe O, Oluwa.

Meter: 7.7.7.7.

Scripture: OD. 30:8

1

mfWa, Jesu fi ara han,

Wa, je k’okan wa mo O

Wa, mu gbogb’ okan gbona,

Wa, bukun wa k’a to lo.

2

Wa, f’aya wa n’isimi,

Wa, k’a d’alabukunfun;

Wa, soro alafia,

Wa, busi igbagbo wa.

3

fWa, le’siyemeji lo,

Wa, ko wa b’a'ti bebe;

Wa, fun okan wa n’ife,

Wa, fa okan wa soke.

4

fWa, so f’okan wa k’o yo,

Wa, wipe “’Wo ni mo yan;”

Wa, p’awon agbo Re mo,

Wa, sure f’agutan Re.