Hymn 601
E jeki a fi gboiya wa si ibi ite ore-ofe ki a le ri anu gba.
Meter: C.M.
Scripture: Heb. 4:16
1
mpIte anu! e je k’a lo
Lati gba adura;
Olorun ’fe y’o sanu fun
Awon t’o nsin nibe.
2
mpIte anu! a, n’ite na
L’ekun wa ti nkunle;
Olorun si nro ’jo 'bukun
Nigba kugba t’a lo.
3
mf’Te anu! eyin mimo ye,
Ite na si sile;
Fi edun yin han Olorun,
Si wa ’di ife Re.
4
A ko le sai fe’te anu,
Niwon bi a ti wa,
pAti onigbowo, titi
Iku y’o pa wa da.
5
mf’Gbana oju Jesu yoo tan
’Mole y’ite na ka,
A ki o si mo aini mo,
A k’y’o wa’te anu.