Hymn 605
Oluwa kiyesi aroye mi.
Meter: L.M.
Scripture: OD. 5:1
1
fOluwa, gbo aroye mi,
Gbo adura ikoko mi;
Lodo Re nikan, Oba mi,
L’emi o ma iranwo.
2
mfL’oro Iwo o gbohun mi;
L’afemojumo ojo na;
Ni odo Re l’emi o wo,
Si O l’emi o gbadura.
3
Sugbon nigb’ ore-ofe Re
Ba mu mi de agbala Re.
Odo Re l’em’ o teju mo,
Nibe un o sin O n’irele.
4
fJe k’awon t’o gbekele O,
ffL’ohun rara wi ayo won:
Je k’awon t’Iwo pamo yo,
Awon t’o fe oruko Re.
5
fSi olododo l’Oluwa
O na owo ibukun Re;
Ojurere Re l’eniyan Re
Yio si fi se asa won.