Hymn 608
Enyin o si saferi mi e o si ri mi ti e ba fi okan nyin wa mi.
Meter: 7s
Scripture: Jer. 29:13
1
mfOluwa, a wa ’do Re
L’ese Re l’a kunle si;
A! ma kegan ebe wa,
Ao wa O lasan bi?
2
L’ona ti O yan fun wa,
L’a nwa O lowolowo;
Oluwa, a ki o lo,
Titi ’Wo o bukun wa.
3
Ranse lat’oro Re wa
Ti o fi ayo fun wa
Je ki emi Re k’o fun
Okan wa ni igbala.
4
Je k’a wa, k’asi ri O,
Ni Olorun Olore;
W’alaisan da ’gbekun si
Ki gbogbo wa yo si O.