Hymn 61
Nibe ni awon igbekun simi po, nwon ko si gbohun amunisin mo.
Meter: 7.7.7.7.
Scripture: Jobu 3:18
1
mfImole, Ojo ‘simi,
Je l’o ku mo wa l’oju
B’igbat’orun iba wo,
Fun ajo onigbagbo
2
mfB’imole ti nrekoja
Oru t’aso bo aye;
Gbogbo nkan dake roro,
N’ipari ojo ‘simi
3
Alafia kun’aye
Ti Olorun mimo ni,
Apere t’inu okan
Ti o bo lowo ese
4
Sibe Emi duro ti
Awon t’o nsin l’asale,
T’o gbe okan won s’oke,
To nsare si ebun na
5
pJesu je k’isimi wa
Je ti ayo ninu Re,
PpTit’okan wa y’o simi,
Nibi ‘simi ailopin