Hymn 610
Nitori Emi ni Oluwa ti o mu o larada.
Meter: 13.13.12.12.
Scripture: Eks. 15:26
fGbo iro ese Jesu, O nkoja lo bayi,
O ni ‘tura f’agbogbe, O ns’awotan arun;
Bo ti so f’alaisan ni leti adagun,
O nwi be nisisiyi, “O nfe ‘wosan bi?”
mfO nfe ‘wosan bi?
O nfe ‘wosan bi?
pWa, alailera, wa;
Wa, elese wa;
fWo omi iye ti nsan,
Omi iwenumo,
Wo inu re, iwo yo si ‘wosan.
fOhun Olugbala ni, ipe anu Re,
Mu igbala ofe wa fun gbogbo eniyan;
O npe gbogbo okan ti eru ese npa,
O nfi ife bere pe: “O nfe ‘wosan bi?”
mfAra nni o, eru ese nwo o l’orun,
O ko ha le wonu omi ni bi o ti nru?
fWo Oluwa nduro lati fun o l’okun,
O si nfi ‘fe bere pe: “O nfe ‘wosan bi?”
mpRan wa lowo Jesu ka gbeke l’oro Re,
Je ki emi iwosan be le wa loni yi,
We abawon ese nu, si s’akoso wa,
So f’okan to nwa o pe: “O nfe ‘wosan bi?”