Hymn 611
Won si to wa lati iha gbogbo wa.
Meter: L.M.
Scripture: Mk. 1:45
1
pJesu, ‘Wo Onisegun nla
T'olokunrun nf’ailera mo
Nigba aisan at’irora
O se dida ara fun won.
2
pAfoju, aro, alaisan,
Won ko sai ri ’toju Re gba,
’Torina, awa s’odo Re,
A ntoro anu Re nikan.
3
pIrora ti ’WO la koja,
Jesu, ’WO le se ’wosan re
Awon to nw’onisegun nla
Jo masai se iwosan won.
4
pOluwa, je ki irora
M’alaisan tubo sun mo O;
Ki owo egba Re kokan
Fa asako sunm’odo Re.
5
crSe ’wosan okan to gb’ogbe
Si gba okan ese wa la;
crF’OPO ilera Re fun wa,
Ki le ma yin O titi lae.