Hymn 612
Nigbati O ri opo eniyan, anu won se E.
Meter: 7.7.7.7.
Scripture: Mat. 9:36
1
mf‘Gbati Jesu wa l’aye,
O nsore, O si nsanu;
fKo s’eni t’o kere ju
Ti ko sai f’anu han fun.
2
mfAwon afoju nyika
Ayaro at’aditi;
fGbogbo won li O nwosan,
O si nbukun gbogbo won.
3
mfO le wo adete san
O f’onje be egberun;
Iji okun ngbo Tire
Oro Re ji oku n’de.
4
mfAwon elese yi ka;
Won nyo lati gb’oro Re
Awon ota Re papa
L’oro Re ya lenu ju.
5
mfF’ife Re han mi, Jesu,
F’Ore-Ofe Re kun mi;
F’owo iwosan to mi,
Sure fun mi, bukun mi.