Hymnize

CAC Hymn Collection

Hymn 614

Nse dida ara gbogbo awon ti esu si n pon loju.

Meter: D.C.M.

Scripture: Ise A. 10:38

1

mfApa Re li ojo wonni

Nwosan, o si ngbala;

O nsegun iku at’aisan,

Ati isa-oku;

crAwon afoju nto o wa,

Aro at’amukun;

Adete, alarun egba:

Gbogbo won r’iwosan.

2

mfAse iwosan ntu jade,

Ti nmu won larada;

Omode at’agbalagba,

Won nri idasile;

crSunmo wa lati bukun wa

Bi ti ojo ’gbani;

Egbegberun n f’owo kan O.

Won nfo soke fayo.

3

mfIWO je Onisegun wa,

Jesu Oba iye;

Tun wa soji, si bukun wa

Nip’ agbara nla Re;

crFi ogbon orun Re kun wa,

SO ope d’ologbon;

Ki gbogbo wa gbohun s’oke

Lati yin O titi.