Hymn 615
Jesu Kristi okan na ni li ana ati li oni, ati titi lae.
Meter: 8.7.8.7.D.
Scripture: Heb. 13:8
1
mfJesu, okan na ni titi
Bi O ti wa nigbani:
Lasan li orun apadi
N dojuko agbara Re,
L’okan awon eniyan Re,
Onjoba titi d’oni:
fTire ni gbogbo agbara,
O nfa ide ese ja.
2
mfJesu, okan na ni titi,
O nwosan titi d’oni,
Ko s’alaisan to le pada
Lai fun n’imularada;
O nwo aisan to buruju,
O sa mo ailera wa,
fO le ru ’banuje wa lo
Bi a ba ko won to wa.
3
mfJesu, okan na ni titi,
Ka sa ma gbe inu Re;
Ko sohun ti o le ya wa
Ninu ife Oluwa;
O le ko aniyan wa lo,
O si le tu wa ninu;
Olugbala to sowon ju,
Ko s’oruko bi Tire.