Hymn 62
Ni ijo mefa ni iwo o sise.
Meter: L.M
Scripture: Eks. 20:9
1
fOjo isimi Olorun,
Ojo ti o dara julo;
Ti Olorun ti fun wa;
K’awa k’o simi ninu re
2
Ijo mefa l’O fi fun wa,
K’a fi se ise wa gbogbo;
Sugbon ojo keje yato,
Ojo ‘simi Olorun ni
3
mfK’a fi ‘se asan wa sile,
Ti awa nse n’ijo mefa;
Mimo ni ise ti ni,
Ti Olorun Oluwa wa.
4
fA para di nissiyi
Ninu ile Olorun wa;
Jek’a korin didun si I,
Li owuro ojo oni.
5
Ni kutukutu ‘jo keje
Ni ojo simi mimo
FfJek’a jumo korin didun,
Je k’a si jumo gbadura.