Hymn 620
Emi ki yio fi nyin sile.
Meter: 7.7.7.7.
Scripture: Jn. 14:18
1
Jesu awa nwo O fun
’Wosan alailera yi
’Wo lo ti se anu nla,
F’abirun let’ adagun.
2
Ko s’onisegun bi Re;
Ti w’ara at’okan san,
’Wo lo ji omobirin
Jairu dide nin’oku.
3
Lasaru ti s’aisan ri,
O ku, a sin i n’boji,
Sugbpn ’wo ’nisegun nla,
J’oku ’jo kerin dide.
4
pJesu jo dari ji wa,
Ba wa wo alaisan yi,
crK’o le dide f’ogo Re,
fKi a le f’ope fun O.
5
fWo ko w’aisan kan ti ri,
Ninu igbe aye Re,
O ti wi nin’ anu Re,
Pe ’leri Re ko ni ye.