Hymnize

CAC Hymn Collection

Hymn 623

Tujuka, a dari ese re ji O.

Meter: 7.7.7.7.

Scripture: Mat. 9:2

1

mfJesu, nigba aye Re,

O ko dekun wo arun;

Igbe irora aisan

Ko kan O k’o bo ’le ri,

2

mfOju anu Re ko gba

K’elese ma je ’rora,

diB’o tile je pe’ya na

To si i fun ese re.

3

mpNinu ija ki emi

Le bo l’owo iparun,

O ko gbagbe p’alafia

To s’eran ara pelu.

4

pB’alaisan ijo wa wo

Lor’ akete irora,

Onisegun Ododo,

Se awotan arun re.

5

F’opo itunu fun u,

K’o le gbe ara le O,

K’o mo pe Iwo nikan

L’O le pa, l’O le gbala.

6

Ma je k’o siyemeji,

Ki irora mu bo ’hun

pFun l’ebun lati wipe

“B’iye, b’iku, ife Re "

7

pK’o le wu O lati wo

Alaisan ijo wa san,

Bi beko, awa mo pe

Fun rere ni ife Re.