Hymn 624
Eniti o si tan gbogbo arun re.
Meter: C.M.
Scripture: OD. 103:3
1
mfEni t’O la ’ju afoju,
Ti O mu ope gbon,
At’ eni t’O da imole,
Fun eni okunkun.
2
Eni t’O le fi agbara
F’awon olokunrun,
Ti O si fi emi iye
pFun awon t’o ti ku.
3
Eni fi ’dasile f’okan,
T’O gb’ eni subu nde,
T’O si pa ibinuje da
S’ orin pelu iyin.
4
fWO Onisegun okan mi,
Si O l’awa nkorin,
Titi aye o fi d’opin,
Tire l’ope O se.