Hymnize

CAC Hymn Collection

Hymn 630

Alabukun li awon ti ko ri Mi, sugbon ti nwon gbagbo.

Meter: 8.8.8.D.

Scripture: Jn. 20:29

1

mpOm’Olorun, a ko ri O,

’Gba t’O wa s’aye, iku yi;

Awa ko ri ibugbe Re;

Ni Nasareti ti a gan,

Sugbon a gbagbo p’ese Re

Ti te ita Re kakiri.

2

pA ko ri O lori igi

T’eyan buburu kan O mo

A ko gbo igbe Re, wipe

“Dariji won, tor’ aimo won”

fSibe, a gbagbo pe: 'ku Re

Mi aye, o si m'orun su.

3

mfA ko duro l'eti 'boji

Nibiti a gbe te O si;

A ko joko ’nu yara ni,

A ko ri O l’oju ona

fSugbon a gbagbo p’angeli

Wipe, “lwo ti ji dide”.

4

mfAkor’awon wonni t’O yan

Lati ri ’goke - r’orun Re;

crWon ko fi iyanu woke

pWon si feru dojubole

Sugbon a gbagbo pe won ri O

Bi O ti n goke lo s’orun.

5

mfIwo njoba l’oke loni,

’Wo si nbukun awon Tire

diImole ogo Re ko tan

Si aginju aye wa yi,

fSugbon, a gba oro Re gbo Jesu,

Olurapada wa.