Hymn 637
Abrahamu si pe oruko ibe na ni Jehofa-jire.
Meter: C.M.
Scripture: Gen. 22:14
1
mfKo to k’awon mimo beru,
Ki won SO ’reti nu:
’Gba won ko reti ranwo Re,
Olugbala y’o de.
2
Nigbati Abraham mu obe,
Olorun ni, “Duro”;
Agbo ti o wa lohun ni,
Y’o dipo omo na.
3
p’Gba Jona ri sinu omi,
Ko ro lati yo mo;
Sugbpn Olorun ran eja,
T’o gbe lo s’ebute.
4
B’iru ipa at’ife yi
Ti po l’oro Re to!
Emi ba ma k’aniyan mi,
Le Oluwa lowo!
5
fE duro de iranwo Re,
B’o tile pe, Duro,
B’ileri na tile fale,
Sugbpn ko le pe de.