Hymn 638
Nitori ti itara ile re ti je mi tan.
Meter: 8.8.8.D.
Scripture: OD. 69:9
mfFun mi n’igbagbp to le so
Oke giga di petele;
Fun mi ni ife adura,
Ti nfe lati tun ’le Re ko;
crK’ife Re bori okan mi,
Ko si gba gbogb’ emi mi kan.
mfMo nfe ife to lagbara,
Mo nfe itara to gbona,
crKi nyo elese n’nu ina,
Ki nja won lowo iparun,
Ki ndari won sod’Olorun
Ki nf’eje Jesu pa ’na won.
mfMo fe ra ’gba to lo pada,
crKi npe laye nitorina,
Ki nlo ara mi fun awon
Ti ko ti mo Olugbala;
Ki nfipe mi han lara won,
Ki nsi ma mi kik’ife Re.
mfGba ebun ati ise mi
S’owo rere Re, Oluwa;
Jeki nma wasu Oro Re,
crKi nwa laye fun ogo Re,
Ki nlo gbogbo akoko mi
N’ikede Ore elese.
mfBu s’okan mi, mu ko gbona,
K’O si f’ife mimo kun un!
crBeni un o lo gbogbo ’pa mi,
Un o f’itara Tire fe won;
Un o si to won si iha Re,
Awon agutan t’O ku fun.