Hymn 64
Oluwa si simi nijo k’eje,
Meter: 8.7.8.7
Scripture: Eks. 20:11
1
fAkoko odun at’osu
Gbogbo won l’Olorun da;
Ojumo ni fun ise wa,
Oru si ni lati sun
2
O si da ojo isimi;
N’nu ‘jo meje, O mu ‘kan,
K’eniyan ba le r’aye se
Ati sin olorun won
3
L’ojo mefa ni k’a sise
B’o ti ye ni ki a se;
L’ojo keje je k’a pejo,
Ni ile Olorun wa
4
L’ojo na yi a ngbadura,
A nkorin didun si I
A si nyin Olorun l’ogo
T’o ju ohun gbogbo lo
5
Nissiyi korin iyin,
T’Olorun Oluwa wa;
FfKorin didun, Korin soke,
Ni yiyin Oluwa wa.