Hymn 641
E ma ru eru omonikeji nyin, ki e si fi be mu ofin Kristi se.
Meter: C.M.
Scripture: Gal. 6:2
1
fAlabukun ni fun ife
Ti ki o je k’a ya;
Bi ara wa jina s’ara,
Okan wa wa l’okan.
2
mfDa opo emi s’ori wa,
Ona t’o la l’a nto;
Nipa ti Jesu l’a si nrin,
Iyin Re l’a nfi han.
3
Awa ba ma rin l’ona RE,
K’a ma si m’ohun kan;
K’a ma fe ’hun kan bikose
Jesu t’a pa fun wa.
4
fK’a sun mo O girigiri
Ati si ona Re;
K’a ma r’ore gba lodo Re,
ffEkun ore-ofe.