Hymnize

CAC Hymn Collection

Hymn 643

Sugbon eyiti o tobi ju ninu won ni ife.

Meter: C.M.

Scripture: I. Kor. 13:13

1

Alafia ni f’okan na

Nibit’ ife gbe wa;

Ife ni o tobi julo

Ninu gbogbo ebun.

2

mfAsan ni gbogbo imo je,

crAsan ni ’beru wa:

Ese y’o bori okan wa

B’ife ko si nibe.

3

Ife l’ondari ese wa

Si ona igboran;

Esu mo yi o nwa riri;

’Tori ko le n’ife.

4

Ife nikan ni y’o r’opin

Igbagbo on ’reti;

Nipa re l’a o ma korin

Loke orun lohun.

5

K’a to pa ago ara ti

Ile okunkun yi;

Iye ife y’o gbe wa fo

LO ri Olorun wa.