Hymnize

CAC Hymn Collection

Hymn 645

Gbogbo nwon fi okan kan wa nibi kan.

Meter: C.M.

Scripture: Ise A. 2:1

1

mfEje k’a yin Olugbala

T’O da wa po l’okan

T’O pase k’a tun jo pade,

Lati wa oju Re.

2

O pase k’a gbe ‘ra wa ro:

Awa jumo nlepa

Ipe giga wa t’o logo

N’nu isokan emi.

3

crEbun t’O fun wa, lokokan

L’awa nfi ayo lo;

Or’ofe na nsan larin wa,

Ninu ife mimo.

4

crEro at’oro wa j’okan

Ife wa si j’okan

Awa wa n’irepo pipe

Li oruko Jesu.

5

A nse ajopin ayo wa,

At’alafia wa,

Alafia t’aye ko mo,

Ayo t’a ko le so.

6

B’idapo wa ninu Jesu

Ba dun bayi laye,

fAyo wa y’o ti tobi to

‘Gba ba yi ‘te Re ka!