Hymn 646
O ti dara, o si ti dun-to fun awon ara lati majumo gbe ni irepo.
Meter: 8.8.8.8.D.
Scripture: OD. 133:1
1
fO ti dara to lati ri
Awon ara ni irepo,
T’ero at’oro won j’okan,
Ti won nfi ’gbagbo at’ife
Jumo nwa ohun ti orun,
Won nkede okiki Jesu.
2
mfOlorun, Olore-ofe,
T’mu Re dun s’isokan wa,
On f ayo busi ’pade wa;
O nf’itura mu wa soji
O ntu’bukun Re sori wa,
O nfun wa n’ibale okan.
3
mfJesu, Okuta igun’le
Je k’ awon t’Emi Re dapo
Ma wa n’nu isokan pipe;
Je k’ a ma gbe ’nu Emi Re
K’a f’apere ’sokan mimo
Lele fun ijo Re nihin.
4
fJe k’a ma fi mo ara wa
F’ebun or’-ofe Re fun wa
Lati ma ya wa si mimo;
Titi ao fi d’eni pipe,
T’ a o ba awon t’oke pade
T’ ao si ni ipo lodo Re.