Hymn 654
Won nyo niwaju re gege bi ayo ikore.
Meter: 8.8.8.8.8.8.
Scripture: Isa. 9:3
1
mfOluwa ’kore, ’Wo l’a yin;
Ileri Re ’gbani ko ye
Orisi igba si nyipo,
Ododun kun fun ore Re;
L’ojo oni, awa dupe,
Je k’iyin gba okan wa kan.
2
mfB’akoko’rugbin mu wa yo;
B’igba erun nmu oru wa;
’Gbat’ owo ojo ba nrinle;
Tab’ igbati ’kore ba pon,
f’WO Oba wa l’a o ma yin;
’WO l’alakoso gbogbo won.
3
fJu gbogbo re lo, nigbati
Owo re fun opo kale
’Gbati ohun ayo gb’ile
B’eda ti nko ire won jo;
ffAwa pelu y’o ma yin O
Oore Re ni gbogbo wa npin.
4
mfOluwa ’kore, Tire ni
Ojo ti nro, orun ti nran;
Irugbin ti a ngbin sile,
Tire l’ogbon ti nmu dagba;
Otun l'ebun Re l’ododun;
Otun n’iyin Re l’enu wa.