Hymn 655
Eniti nji ekun rin lo, ti o si gbe Irugbin lowo, loto yio fi ayo pada wa, yio si ru iti re.
Meter: 7.7.7.7.D.
Scripture: OD. 126:6
1
fWa, eyin Olope wa,
Gbe orin ikore ga,
Ire gbogbo ti wole
K’otutu oye to de;
mfOlorun Eleda wa,
ffL’o ti pese f’aini wa;
Wa k’arele Olorun
Gbe orin ikore ga.
2
mfOko Olorun l’a je
Lati s’eso iyin Re
Alikama at'epo,
Ndagba f’aro tab’ayo
crEhu su, ipetele
Siri oka si kehin;
pOluwa ’kore mu wa
Je eso rere fun O.
3
mfN'tori Olorun wa mbo
Y’o si kore Re sile;
On o gbon gbogbo panti
Kuro l’oko Re njona;
Y’o f ase f’awon angel’
Lati gba epo s’ina;
Lati ko Alikama
Si aba Re titi lae.
4
Beni, ma wa, Oluwa
Si ikore, ikeyin
Ko awon eeyan Re jo
Kuro l’ese at’aro;
So won di mimo laelae
Ki won le maa ba O gbe
Wa t’Iwo t’angeli Re
Gbe orin ikore ga.