Hymnize

CAC Hymn Collection

Hymn 657

Niwon igba ti aye yio wa, igba irugbin ati ikore ki yio dopin.

Meter: 7.6.7.6.D.

Scripture: Gen. 8:22

1

Aroko, a funrugbin

Sinu oko gbogbo,

crSugbpn owo Olorun

L’o mu ’rugbin dagba;

O ran otu at’oru

Lati mu eso pon,

Efufu ati orun,

At’ojo t’o nrinle.

CHORUS

mfEbun rere gbogbo

Lati orun wa ni;

Sope f’Oluwa, e sope

Fun gbogbo ife Re.

2

fOn nikan li Eleda

Orun ati aye;

O fun itanna l’ewa,

O mu irawo tan;

Iji gba ohun Re gbo,

O mbo awon eye;

Paapaa awa omo Re

L’O mbo lojojumo.

3

fBaba, a sope fun O,

F’ohun rere gbogbo,

Fun ’gba ’rugbin on ’kore

F’emi ’lera, onje;

Gba ebun ti a mu wa

Fun iseun-ife Re.

Si gba okan ope wa,

’Wo sa fe eyi ju.