Hymn 659
Emi ko pa iseun ife Re ati otito Re kuro lodo ijo nla ni.
Meter: 8.7.8.7.D.
Scripture: OD. 40:10
1
fOluwa, a gbe okan wa
Si O n’nu orin iyin;
A m’ore ope wa fun O
Pelu iho ayo nla;
Gbogbo papa f’ewa bora
Awon oke nho f’ayo
Oka po l’afonifoji
Tobe ti won fi nkorin.
2
mfLoni, ojo ikore wa,
Awa jewo ore Re,
fAwa f’ope mu ebun wa,
Akoso ibukun Re
’Wo l’o nfi ore-ofe bo
Okan awa eda Re,
’Wo ti npese onje ojo,
Fi onje orun bo wa.
3
crA nfarada oru ojo,
Laalaa a si ma su-ni;
mfSugbon nigbati oorun wo
'Simi de fun alaare;
mpSe wa l’eni itewogba,
’Gbat’ angeli ba nkore,
K’a je alikama Kristi
Ti O n y’o to si aba.
4
mfAbukun n’ile Olorun
’ Bit’ awon mimo wa lae
Papa wura teju nibe
Odo re ndan bi Kristal,
ffOrin egbe mimo t’ohun
Dapo mo tiwa loni;
’Bukun orin ’kore na po
Ti a o maa ko titi.