Hymn 661
Awon enia mimo Re yio si mafi ibukun fun O.
Meter: 6.6.6.6.D.
Scripture: OD. 145:10
1
fOgo, iyin, ola,
Fun Olugbala wa
T’o da emi wa si
Titi d’ojo oni
Ayo kun okan wa
Fun anfani nla yi
Lati sise fun O
N’nu ogba Re laye.
2
fA dupe fun ’toni
On agbara t’emi
At’ebun ife nla
Ti o fi so wa po,
Olusagutan wa,
Tewo gba iyin wa;
Nitori anu Re
Se wa l’okan laelae.
3
mpBukun wa, Oluwa,
Loni ajodun wa,
Ran ami Re si wa
K’a layo n’nu ’sin Re
Ka si s’aseyori
N’nu ise isin wa
K’a si fi Jesu se
Igbekele wa lae.
4
mfEleda, Oluwa,
Orisun ’gbala wa,
diSe waye f’ajodun
Ti ibugbe loke;
N’ipari ajo wa
N’nu aye osi yi,
K’a le ni ibugbe
Lodo Re Oluwa.