Hymn 662
Nitori ohun gbogbo odo Re ni o ti wa, ati ninu ohun owo Re li awa tifi fun o.
Meter: 8.8.8.4.
Scripture: I Kro. 29:14
fOluwa orun oun aye,
‘Wo n’iyin at’ope ye fun fun:
Bawo la ba ti fe O to!
Onibu ore.
Orun ti nran, at’afefe,
Gbogbo eweko nso ’ fe Re;
’Wo l’O nmu irugbin dara,
Onibu ore.
Fun ara lile wa gbogbo,
Fun gbogbo ibukun aye
Awa yin O a si dupe;
Onibu ore.
pO ko du wa li Omo Re,
O fi fun aye ese yi,
Pelu Re l’ofe l’o nfun wa
L’ohun gbogbo.
mfO fun wa l’Emi Mimo Re.
Emi iye at’ agbara,
O ro ’jo ekun ’bukun Re
Le wa l’ori.
pFun idariji ese wa,
crAti fun ireti orun,
fKil’ ohun t’a ba fifun O?
Onibu ore.
Owo ti a nna ofo ni,
Sugbpn eyi t’a fi fun O,
O je isura tit’ aye.
Onibu ore.
Ohun t’a bun O, Oluwa
cr’Wo O san le pada fun wa,
fL’ayo l’a o ta O lore
Onibu ore.
Ni odo Re l’a ti san wa,
Olorun Olodumare,
Je k’ale ba O gbe titi;
Onibu ore.