Hymn 663
Ife ni Olorun.
Meter: 8.6.8.6.8.8.8.6.
Scripture: I Jn. 4:8
1
fE wa k’a jo jumo korin,
Ife ni Olorun
Orun, aye mu yin won wa
Ife ni Olorun!
Ki gbogbo okan ji kuro
Ninu ese ki won f’ayo
Korin didun n’tori Jesu,
Ife ni Olorun!
2
E so ni gbogbo agbaye
Ife ni Olorun!
N’nu Krist’ l’ekun ’rapada wa
Ife ni Olorun!
Eje Re le w’ese wa nu,
Emi Re s’oru wa d’osan
O nto ’kan wa lati so pe
Ife ni Olorun!
3
Ayo ni ipin wa nihin
Ife ni Olorun!
Okan wa nyo si ’leri Re
Ife ni Olorun!
Orun at’abo wa losan
O si mba wa gbe ni oru
On yo wa pelu wa titi
Ife ni Olorun!
4
Ni Sion lao tun korin yi
Ife ni Olorun!
ffOrin t’yo ga soke julo
Ife ni Olorun!
Titi aye ainipekun
Pelu awon mimo loke
Orin wa to dun julp ni:
Ife ni Olorun!