Hymn 666
Oluwa li Oluso-agutan mi.
Meter: 8.7.8.7.
Scripture: OD. 23:1
1
fJesu l’Olus’agutan mi,
Ore Eni ti ki ye!
Ko s’ewu bi mo je Tire,
T’On si je t’emi titi.
2
fNib’ odo omi iye nsan
Nibe l’O nm’ okan mi lo,
Nibiti oko tutu nhu,
L’O nf onje orun bo mi.
3
pMo ti fi were sako lo,
crN’ife O si wa mi ri;
diL’ejika Re l’O gbe mi si,
fO f’ayo mumi wa’le.
4
pNko beru ojiji iku,
crB’iwo bawa l’odo mi;
Ogo Re ati opa Re
Awon l’o ntu mi ninu.
5
mfIwo te tabili fun mi;
’Wo d’ororo s’ori mi;
A! ayo na ha ti PO to
Ti nt’ odo Re wa ba mi?
6
fBe l’ojo aye mi gbogbo
Ore Re ki o ye lae
Olus’agutan, un o yin O
Ninu ile Re titi.