Hymnize

CAC Hymn Collection

Hymn 669

Awa feran Re; nitori On li o ko feran.

Meter: D.C.M.

Scripture: I Jn. 4:19

1

mfJesu Oluwa a fe o,

’Tori gbogbo ebun

Nt’owo Re da lait’ oke wa

B’iri si gbogb’ aye;

A yin O n’tori ’wonyi,

K’ise fun won nikan,

Ni awon omo-odo Re

Se ngb’ adura si O.

2

pAwa fe O, Olugbala,

’Tori ’gbat’ a sako,

Iwo pe okan wa pada

Lati t’ona iye;

’Gba t’a wa ninu okunkun,

Taa ri ninu ese,

cr’Wo ran imole Re si wa

Lati f’ona han wa.

3

fBaba orun awa fe O,

Nitori ’Wo fe wa

’Wo ran Omo Re lati ku,

Ki awa le n’iye;

‘Gbat’a wa l’abe ’binu Re

'Wo fun wa n’ireti;

crBi ese t’a da ti po to

Be l’o ndariji wa.