Hymnize

CAC Hymn Collection

Hymn 676

On Opa mi mo ninu ago Re.

Meter: 7.7.7. D.

Scripture: OD. 27:5

1

mpApata ayeraye,

Se ibi isadi mi;

crJe ki omi on eje

T'osan lati iha Re

Se iwosan f’ese mi,

K'o si so mi di mimo.

2

mfK’ise ise oWO mi

L’o le mu ofin Re se,

B’itara mi ko l’are

T’omije mi nsan titi,

Won ko to fun etutu

'Wo nikan l'o le gbala.

3

pKo s'ohun ti mo mu wa,

Mo ro mo agbelebu;

Mo wa k’od'aso bo mi,

Mo nwo O fun iranwo;

Mo wa sib'orisun ni,

crWe mi, Olugbala mi.

4

mp'Gbati emi mi ba pin,

pT'iku ba p'oju mi de,

crTi mba lo s’aye aimo,

Ki nri O n’ite ’dajo;

diApata ayeraye

ppSe ibi isadi mi.